Aisaya 29:14-18 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nítorí náà n óo tún ṣe ohun ìyanu sí àwọn eniyan wọnyi,ohun ìyanu tí ó jọni lójú.Ọgbọ́n yóo parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu,ìmọ̀ràn yóo sì parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀mọ̀ràn níkùn.”

15. Àwọn tí wọ́n fi èrò wọn pamọ́ fún OLUWA gbé;àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ́ iṣẹ́ òkùnkùn,tí ń wí pé, “Ta ló rí wa?Ta ló mọ̀ wá?”

16. Ẹ dorí gbogbo nǹkan kodò.Ṣé eniyan lè sọ amọ̀kòkò di amọ̀?Kí nǹkan tí eniyan ṣe, wí nípa ẹni tí ó ṣe é pé:“Kìí ṣe òun ló ṣe mí.”Tabi kí nǹkan tí eniyan dá sọ nípa ẹni tí ó dá a pé:“Kò ní ìmọ̀.”

17. Ṣebí díẹ̀ ṣínún ló kùtí a óo sọ Lẹbanoni di ọgbà igi elésoa óo sì máa pe ọgbà igi eléso náà ní igbó.

18. Ní ọjọ́ náà, odi yóo gbọ́ ohun tí a kọ sinu ìwé,ojú afọ́jú yóo ríran, ninu òkùnkùn biribiri rẹ̀.

Aisaya 29