5. Wọ́n tẹ́ tabili, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sílẹ̀wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu.Ariwo bá ta pé“Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin ológun!Ẹ fepo pa asà yín.”
6. Nítorí OLUWA wí fún mi pé:“Lọ fi aṣọ́nà ṣọ́ ojú ọ̀nà,kí ó máa kéde ohun tí ó bá rí.
7. Nígbà tí ó bá rí àwọn ẹlẹ́ṣintí wọn ń bọ̀ ní meji-meji, bí ó bá rí ití àwọn kan gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,tí àwọn kan gun ràkúnmí,kí ó fara balẹ̀ dáradára,kí ó dẹtísílẹ̀ dáradára.”
8. Ẹni tí ń ṣọ́nà kígbe pé:“OLUWA mi, lórí ilé-ìṣọ́ ni èmi í dúró sí lojoojumọ,níbi tí a fi mí ṣọ́, ni èmi í sì í wà ní òròòru.
9. Ẹ wò ó! Àwọn ẹlẹ́ṣin kan ń bọ̀,wọ́n fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ní meji-meji!”“Ẹ gbọ́! Ìlú Babiloni ti wó! Ó ti wó!Pẹlu gbogbo àwọn oriṣa rẹ̀,ó ti wó lulẹ̀ patapata.”