1. Àsọtẹ́lẹ̀ nípa aṣálẹ̀ etí òkun nìyí:àjálù kan ń já bọ̀ láti inú aṣálẹ̀,láti ilẹ̀ tí ó bani lẹ́rù,ó ń bọ̀ bí ìjì líle tí ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá aṣálẹ̀.
2. Ìran tí a fi hàn mí yìí le:Àwọn oníjàgídíjàgan lọ digun kó ìkógun,abanǹkanjẹ́ sì ba nǹkan jẹ́.Ẹ̀yin ará Elamu, ẹ gòkè lọ!Ẹ̀yin ará Media, ẹ múra ogun!Mo ti fòpin sí òṣé ati ìjìyà tí Babiloni kó bá gbogbo eniyan.