20. Yóo jẹ́ àmì ati ẹ̀rí fún OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe OLUWA nítorí àwọn aninilára, OLUWA yóo rán olùgbàlà tí yóo gbà wọ́n sí wọn.
21. OLUWA yóo sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ará Ijipti, wọn óo sì mọ OLUWA nígbà náà. Wọ́n yóo máa sin OLUWA pẹlu ẹbọ ati ẹbọ sísun; wọn óo jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, wọn yóo sì mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ.
22. OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ará Ijipti ṣugbọn yóo wò wọ́n sàn, wọn yóo pada sọ́dọ̀ OLUWA, yóo gbọ́ adura wọn, yóo sì wò wọ́n sàn.