9. Tó bá di ìgbà náà, àwọn ìlú olódi ńláńlá wọn yóo dàbí àwọn ìlú tí àwọn ará Hifi ati àwọn ará Amori sá kúrò níbẹ̀, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbógun tì wọ́n; gbogbo rẹ̀ yóo di ahoro.
10. Nítorí pé ẹ ti gbàgbé Ọlọrun olùgbàlà yín,ẹ kò ranti Àpáta tí ó jẹ́ ààbò yín.Nítorí náà bí ẹ tilẹ̀ gbin igi dáradára tí ẹ̀ ń bọ ọ́,tí ẹ sì gbin òdòdó àjèjì tí ẹ̀ ń sìn ín;
11. wọn ìbáà hù lọ́jọ́ tí ẹ gbìn wọ́n,kí wọ́n yọ òdòdó ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí ẹ lọ́ wọnsibẹsibẹ kò ní sí ìkórèní ọjọ́ ìbànújẹ́ ati ìrora tí kò lóògùn.
12. Ẹ gbọ́ ariwo ọ̀pọ̀ eniyan,wọ́n ń hó bí ìgbì òkun.Ẹ gbọ́ ìró àwọn orílẹ̀-èdèwọ́n ń hó bíi ríru omi òkun ńlá.