Aisaya 17:10-14 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Nítorí pé ẹ ti gbàgbé Ọlọrun olùgbàlà yín,ẹ kò ranti Àpáta tí ó jẹ́ ààbò yín.Nítorí náà bí ẹ tilẹ̀ gbin igi dáradára tí ẹ̀ ń bọ ọ́,tí ẹ sì gbin òdòdó àjèjì tí ẹ̀ ń sìn ín;

11. wọn ìbáà hù lọ́jọ́ tí ẹ gbìn wọ́n,kí wọ́n yọ òdòdó ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí ẹ lọ́ wọnsibẹsibẹ kò ní sí ìkórèní ọjọ́ ìbànújẹ́ ati ìrora tí kò lóògùn.

12. Ẹ gbọ́ ariwo ọ̀pọ̀ eniyan,wọ́n ń hó bí ìgbì òkun.Ẹ gbọ́ ìró àwọn orílẹ̀-èdèwọ́n ń hó bíi ríru omi òkun ńlá.

13. Ìró àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ti omi òkun ńláṣugbọn OLUWA yóo bá wọn wí wọn óo sì sá lọ.Wọn óo dàbí ìràwé tí afẹ́fẹ́ ń gbé lọ lórí òkè,ati bí eruku tí ìjì líle ń fẹ́ kiri.

14. Ìdágìrì yóo bá wọn ní ìrọ̀lẹ́,kí ilẹ̀ tó mọ́ wọn kò ní sí mọ́;bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn tí wọ́n fogun kó wa,bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù lọ.

Aisaya 17