Aisaya 13:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ìran tí Aisaya ọmọ Amosi rí sí Babiloni:

2. Ẹ ta àsíá ní orí òkè gíga,ẹ gbóhùn sókè sí wọn.Ẹ juwọ́, kí àwọn ológun gba ẹnu ibodè àwọn ọlọ́lá wọlé.

3. Èmi pàápàá ti pàṣẹ fún àwọn tí mo yà sọ́tọ̀,mo ti pe àwọn akọni mi, tí mo fi ń yangàn,láti fi ibinu mi hàn.

4. Gbọ́ ariwo lórí òkè, bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan,gbọ́ ariwo ìdàrúdàpọ̀ ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ń péjọ pọ̀!OLUWA àwọn ọmọ ogunní ń kó àwọn ọmọ ogun jọ fún ogun.

Aisaya 13