3. Kí ni ẹ óo ṣe lọ́jọ́ ìjìyà yíntí ìparun bá dé láti òkèèrè?Ta ni ẹ óo sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́?Níbo ni ẹ óo kó ọrọ̀ yín sí?
4. Kò sí ohun tí ó kù àfi kí ẹ kú lójú ogun,tabi kí ẹ ká góńgó láàrin àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú.Sibẹsibẹ inú OLUWA kò ní rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.
5. Háà! Asiria!Orílẹ̀-èdè tí mò ń lò bíi kùmọ̀, ati bíi ọ̀pánígbà tí inú bá bí mi.