25. Nítorí pé láìpẹ́, ibinu mi si yín yóo kásẹ̀ nílẹ̀, n óo sì dojú ibinu mi kọ wọ́n láti pa wọ́n run.
26. Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, n óo fi ọ̀pá mi nà wọ́n, bí ìgbà tí mo na àwọn ará Midiani ní ibi àpáta Orebu. Ọ̀pá rẹ̀ yóo wà lórí òkun. Yóo tún gbé e sókè bí ó ti ṣe ní Ijipti.
27. Ní ọjọ́ náà, a óo gbé ẹrù tí ó dì lé ọ lórí kúrò, a óo sì fa àjàgà rẹ̀ dá kúrò lọ́rùn rẹ.”
28. Ó ti kúrò ní agbègbè Rimoni,ó ti dé sí Aiati;ó kọjá ní Migironi,ó kó ẹrù ogun rẹ̀ jọ sí Mikimaṣi.
29. Wọ́n sọdá sí òdìkejì odòwọ́n sùn ní Geba di ọjọ́ keji.Àwọn ará Rama ń wárìrì,àwọn ará Gibea, ìlú Saulu sá lọ.
30. Kígbe! Ìwọ ọmọbinrin Galimu.Fetí sílẹ̀ ìwọ Laiṣa,kí Anatoti sì dá a lóhùn.
31. Madimena ń sá lọ,àwọn ará Gebimu ń sá àsálà.
32. Ní òní olónìí, yóo dúró ní Nobu,yóo di ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn òkè Sioni,àní òkè Jerusalẹmu.
33. Ẹ wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun,yóo gé àwọn ẹ̀ka igi náà pẹlu agbára tí ó bani lẹ́rù.Yóo gé àwọn tí ó ga fíofío lulẹ̀,yóo sì rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀.
34. Yóo fi àáké gé àwọn igi igbó tí ó dí,Lẹbanoni pẹlu gbogbo igi ńláńlá rẹ̀ yóo sì wó.