Títù 3:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Sa gbogbo agbára rẹ láti ran Sénà agbẹjọ́rò àti Àpólò lọ́wọ́ nínú ìrìnàjò wọn. Rí i dájú pé wọn ní ohun gbogbo tí wọn nílò.

14. Àwọn ènìyàn nílò láti kọ́ bí a tí ń fi ara ẹni jìn sí iṣẹ́ rere kí wọn baà le pèsè ohun kòsémánìí fún ara wọn, nípa èyí, wọn kì yóò jẹ́ aláìléso.

15. Gbogbo àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ mi kí ọ. Bá mi kí àwọn tí ó fẹ́ wa nínú ìgbàgbọ́. Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.

Títù 3