Sekaráyà 8:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jérúsálẹ́mù, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó.

5. Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdé-bìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.”

6. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Bí ó bá ṣe ìyanú ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyánú ni ojú mi bí?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

Sekaráyà 8