Sekaráyà 7:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Sekaráyà wá, wí pé:

9. “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: ‘Ṣe ìdájọ́ òtítọ́, kí ẹ sì ṣe àánú àti iyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀.

10. Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tàlákà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbérò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀.’

Sekaráyà 7