Sekaráyà 10:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Èmi ó sì tún mú wọn padà kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítìpẹ̀lú, èmi ó sì ṣà wọn jọ kúrò ni ilẹ̀ Áṣíríà:èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ Gílíádì àti Lébánónì; aa kì yóò sì rí àyè fún wọn bí ó ti yẹ.

11. Wọn yóò sì la òkun wàhálà já,yóò sì lu rírú omi nínú òkun,gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ,a ó sì rẹ ìgbéraga Áṣíríà ṣílẹ̀,ọ̀pá aládé Éjíbítì yóò sí lọ kúrò.

12. Èmi ó sì mú wọn ní agbára nínú Olúwa;wọn ó sì rìn sókè rìn sódò ni orúkọ rẹ̀,”ni Olúwa wí.

Sekaráyà 10