1. Ẹ bèèrè òjò nígbà àrọ̀kúrò ni ọwọ́ Olúwa; Olúwa tí o dá mọ̀nàmọ́ná,tí ó sì fi ọ̀pọ̀ òjò fún ènìyàn,fún olúkúlúkù koríko ní pápá.
2. Nítorí àwọn òrìṣà tí sọ̀rọ̀ asán,àwọn aláfọ̀ṣẹ sì tí rí èké,wọn sì tí rọ àlá èké;wọ́n ń tu ni nínú láṣán,nítorí náà àwọn ènìyàn náà ṣáko lọ bí àgùntàn,a ṣẹ wọn níṣẹ̀ẹ́, nítorí Olùṣọ́àgùntàn kò sí.
3. “Ìbínú mi ru sí àwọn darandaran,èmi o sì jẹ àwọn olórí níyànítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti bẹ agbo rẹ̀,ilé Júdà wò,yóò ṣi fi wọn ṣe ẹṣin rẹ̀ dáradára ní ogun.