Sáàmù 95:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Tirẹ̀ ni òkun, nítorí òun ni ó dá aàti ọwọ́ Rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

6. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a forí balẹ̀ kí a sìn-ín,Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú Olúwa ẹni tí ó dá wa;

7. Nítorí òun ni Ọlọ́run waàwa sì ni ènìyàn pápá Rẹ̀,àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ Rẹ̀Lónìí ti ìwọ bá gbọ́ ohùn Rẹ̀,

8. Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Méríbà,àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ni Másà ni ihà,

9. Nígbà ti àwọn baba yin dán mi wòti wọn wádìí mi,ti wọn sì ri iṣẹ́ mi

Sáàmù 95