Sáàmù 91:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,

6. Tàbí fún àjàkálẹ̀-àrùn tí ń rìn kiri ni òkùnkùn,tàbí fún ìparun ti ń rin kirí ni ọ̀sán gangan.

7. Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ Rẹ,ẹgbàarùn ún ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹṣùgbọ́n kì yóò sún mọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ

8. Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú Rẹàti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

9. Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò Rẹ,ìwọ fi Ọ̀ga Ògo ṣe ibùgbé Rẹ.

10. Búburú kan ki yóò subu lù ọ́Bẹ́ẹ̀ ni àrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé Rẹ.

11. Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì nípa tìrẹláti pa ọ́ mọ ní gbogbo ọ̀nà Rẹ;

Sáàmù 91