4. Òun yóò fi ìyẹ́ Rẹ̀ bò mí,àti ni abẹ́ ìyẹ́ Rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;òtítọ́ Rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.
5. Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,
6. Tàbí fún àjàkálẹ̀-àrùn tí ń rìn kiri ni òkùnkùn,tàbí fún ìparun ti ń rin kirí ni ọ̀sán gangan.
7. Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ Rẹ,ẹgbàarùn ún ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹṣùgbọ́n kì yóò sún mọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ
8. Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú Rẹàti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.