4. Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú Rẹ,bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
5. Ìwọ gbá ènìyàn dánù nínú oorun ikú;wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
6. Lótìítọ́ ní òwúrọ́ ó yọ tuntunní àsálẹ́ ní yóò gbẹ tí yóò sì Rẹ̀ dànù.
7. A pa wá run nípa ìbínú Rẹnípa ìbínú Rẹ ara kò rọ̀ wá.
8. Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú Rẹ,àti ohun ìkọ̀kọ̀ wà nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú Rẹ,
9. Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú Rẹ;àwa n lo ọjọ wá lọ bí àlá ti a ń rọ́.