Sáàmù 86:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbọ́, Olúwa, kí o sì dà mí lóhùn,nítorí mo jẹ́ talákà àti aláìní.

2. Dáàbòbò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:ìwọ ní Ọlọ́run mi,gbà ìránṣẹ́ Rẹ làtí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

3. Ṣàánú fún mi, Olúwa,nítorí èmi ń pe ọ́ ní gbogbo ọjọ́.

4. Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ Rẹ,nítorí ìwọ, Olúwa,ní mo gbé ọkan mí sókè sí.

5. Ìwọ ń daríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn ti ń ké pè ọ́,

Sáàmù 86