Sáàmù 82:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,ó ṣe ìdájọ́ láàárin àwọn “ọlọ́run òrìṣà”:

2. “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìsòdodokí ó sì ṣe ojú ìṣájú sí àwọn ènìyàn búburú?

3. Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.

4. Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;gbà wọ́n kùró lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.

Sáàmù 82