1. Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára waẸ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jákọ́bù!
2. Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wátẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.
3. Ẹ fún ìpè ni oṣù tuntunàní nígbà ti a yàn;ní ọjọ́ àjọ wa ti ó ni ìrònú.
4. Èyí ni àṣẹ fún Ísírẹ́lì,àti òfin Ọlọ́run Jákọ́bù.