Sáàmù 79:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ o máa bínú títí láé?Yóò ti pẹ́ tó ti òwú Rẹ̀ yóò ha jò bi iná?

6. Tú ìbínú Rẹ̀ jáde sí orílẹ̀-èdètí kò ní ìmọ̀ Rẹ,lórí àwọn ìjọbatí kò pe orúkọ Rẹ;

7. Nítorí wọ́n ti run Jákọ́bùwọ́n sì sọ ibùgbé Rẹ̀ di ahoro

8. Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùnjẹ́ kí àánú Rẹ yà kánkán láti bá wa,nítorí ti a Rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.

9. Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa,fún ògo orukọ Rẹ;gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnítorí orúkọ Rẹ.

Sáàmù 79