9. Àwọn ọkùnrin Éfúráímù, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun,wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun
10. Wọ́n kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin Rẹ̀
11. Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe,àwọn ìyanu tí ó ti fi hàn wọ́n.
12. O ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Éjíbítì, ní agbégbé Síónì
13. O pín òkun níyà, ó sì mú wọn kọjáó mù kí ó nà dúró bá ebè
14. Ní ọ̀ṣán ó fi ìkúùku àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọnàti ní gbogbo òru pẹ̀lú, ìmọ̀lẹ̀ ìná.
15. Ó sán àpáta ní ihàó si fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀bí ẹni pé láti inú ibú wá.