Sáàmù 78:59-64 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

59. Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn,inú bí i gidigidi;ó kọ Ísírẹ́lì pátapáta.

60. Ó kọ àgọ́ Ṣílò sílẹ̀,àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn.

61. Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára Rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn,dídán ògo Rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.

62. Ó fi àwọn ènìyàn Rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,ó sì bínú sí àwọn ohun ìní Rẹ̀.

63. Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn,àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:

64. A fi àlùfáà wọn fún idà,àwọn opó wọn kò sì le è sunkún.

Sáàmù 78