5. Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jákọ́bùo sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Ísírẹ́lì,èyí tí ó páláṣẹ fún àwọn baba ńlá waláti kọ́ àwọn ọmọ wọn,
6. Nítorí náà àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́nbẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí i bítí yóò dìde ti wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn
7. Nígbà náà ni wọn o fi ìgbẹ̀kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́runwọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́runṣùgbọ́n wọn o pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́.
8. Wọn ò ní dàbí àwọn baba ńlá wọnìran aláyà líle àti ọlọ́tẹ̀tí ọkàn wọn kò sòòtọ̀ si oloore.