Sáàmù 78:44-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

44. Ó ṣọ omi wọn dí ẹ̀jẹ̀;wọn kò le mú láti odò wọn.

45. Ó rán ọ̀wọ́ ẹṣinṣin láti pa wọ́n run,àti ọpọlọ tí ó bá wọn jẹun.

46. Ó fi ọkà wọn fún láńtataàwọn irè oko wọn fún eṣú

47. Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́ó bá èso sìkàmore wọn jẹ́

48. Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyínagbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná

49. Ó mú kíkorò ìbínú Rẹ̀ wá sí wọn lára,ìrunú àti ikáánú, àti ìpọ́njú,nípa rírán ańgẹ́lì apanirun sí wọn.

50. Ó pèṣè ipa fún ìbínú Rẹ̀òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikúṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-àrùn

51. Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin ÉjíbítìOlórí agbára wọn nínú àgọ́ Ámù

Sáàmù 78