Sáàmù 78:39-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Ó ránti pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò le padà.

40. Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ síi ní ihàwọn mú-un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro!

41. Síwájú àti síwájú wọn dán Ọlọ́run wò;wọ́n mú ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì bínú.

42. Wọ́n kò rántí agbára Rẹ̀:ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára,

43. Ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ hàn ní Éjíbítì,àti iṣẹ́ àmì Rẹ ni ẹkùn Sáónì

44. Ó ṣọ omi wọn dí ẹ̀jẹ̀;wọn kò le mú láti odò wọn.

45. Ó rán ọ̀wọ́ ẹṣinṣin láti pa wọ́n run,àti ọpọlọ tí ó bá wọn jẹun.

46. Ó fi ọkà wọn fún láńtataàwọn irè oko wọn fún eṣú

Sáàmù 78