Sáàmù 78:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe,àwọn ìyanu tí ó ti fi hàn wọ́n.

12. O ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Éjíbítì, ní agbégbé Síónì

13. O pín òkun níyà, ó sì mú wọn kọjáó mù kí ó nà dúró bá ebè

14. Ní ọ̀ṣán ó fi ìkúùku àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọnàti ní gbogbo òru pẹ̀lú, ìmọ̀lẹ̀ ìná.

15. Ó sán àpáta ní ihàó si fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀bí ẹni pé láti inú ibú wá.

16. O mú ìṣàn omi jáde láti inú àpátaomi sìṣsàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò

17. Wọ́n sì tún tẹ̀ṣíwájú láti dẹ́sẹ̀ sí iní ìsọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá ògo ní àgìnjú.

18. Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wònípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún

19. Wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, wí pé“Ọlọ́run ha lè tẹ tábìlì ní aṣálẹ̀?

20. Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,odò sì ṣàn lọ́pọ̀lọpọ̀ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹó ha le pèṣè ẹran fún àwọn ènìyàn Rẹ̀”

21. Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;iná Rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jákọ́bù,ìbínú Rẹ̀ sì rú sí Ísírẹ́lì,

Sáàmù 78