Sáàmù 73:19-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìíbí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọn pátapáta!

20. Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí,bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa,ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.

21. Nígbà tí inú mi bàjẹ́àti ọkàn mi sì korò,

22. Mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye;mo jẹ́ ẹranko ní ìwájú Rẹ.

23. Ṣíbẹ̀ mo wà pẹ̀lú Rẹ nígbà gbogbo;ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.

Sáàmù 73