Sáàmù 72:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Kí orúkọ Rẹ̀ kí o wà títí láé;orúkọ Rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọn bí òòrùn yóò ti pẹ́ tó;wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nipaṣẹ̀ Rẹ.Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún.

18. Olùbùkún ní Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́li,ẹnìkan ṣoṣo tí ó n ṣe ohun ìyanu.

19. Olùbùkun ni orúkọ Rẹ tí ó lógo títí láé;kí gbogbo ayé kún fún ògo Rẹ.Àmín àti Àmín.

20. Èyí ni ìpàrí àdúrà Dáfídì ọmọ Jéṣè.

Sáàmù 72