Sáàmù 71:22-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Èmi yóò fi dùùrù mi yìnfún òtítọ́ Rẹ, Ọlọ́run mi;èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrùìwọ ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.

23. Ètè mi yóò kígbe fún ìyìnnígbà tí mo bá kọrín ìyìn sí ọ:èmi, ẹni tí o ràpadà.

24. Ahọ́n mí yóò sọ ti òdodo Rẹ ní gbogbo ọjọ́,fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí láraa sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.

Sáàmù 71