9. Ọlọ́run Olódodo,Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn,tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburútí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.
10. Aṣà mi ní Ọlọ́run tí ó gajù,ẹni tí ń dáàbò bo àwọn ẹni gíga nípa ti èmi.
11. Ọlọ́run ni onídàájọ́ tòótọ́,Ọlọ́run tí ń sọ ìrúnú Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.
12. Bí kò bá yípadà,òun yóò pọ́n idà Rẹ̀ múó ti fa ọrun Rẹ̀ le náó ti múra Rẹ̀ sílẹ̀
13. Ó ti pèṣè ohun ìjà ikú sílẹ̀;ó ti pèṣè ọfà iná sílẹ̀.