31. Eléyìí tẹ Ọlọ́run lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo Rẹ̀ àti bàtà Rẹ̀.
32. Àwọn òtòsì yóò rí wọn yóò sì yọ̀:Ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yin yóò sì wà láàyè!
33. Olúwa, gbọ́ ti aláìníkí o sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.
34. Kí ọ̀run àti ayé yìn ín,òkun àti àwọn tí ń gbé inú Rẹ̀,
35. Nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Síónì làyóò sì tún àwọn ìlú Júdà wọ̀nyí kọ́.Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀,kí wọn ó lè máa níi ni ilẹ̀ ìní
36. Àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún Rẹ̀,àwọn ti ó fẹ́ orúkọ Rẹ ní yóò máa gbé inú Rẹ̀.