Sáàmù 69:30-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run gaèmi yóò fí ọpẹ́ gbé orúkọ Rẹ̀ ga.

31. Eléyìí tẹ Ọlọ́run lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo Rẹ̀ àti bàtà Rẹ̀.

32. Àwọn òtòsì yóò rí wọn yóò sì yọ̀:Ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yin yóò sì wà láàyè!

33. Olúwa, gbọ́ ti aláìníkí o sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.

34. Kí ọ̀run àti ayé yìn ín,òkun àti àwọn tí ń gbé inú Rẹ̀,

Sáàmù 69