1. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, gbogbo ayé!
2. Ẹ kọrin ọ̀lá orúkọ Rẹ̀;Ẹ fún un ní ìyìn, ògo,
3. Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé,ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ Rẹ̀!Nípa ọ̀pọ̀ agbára Rẹ ni àwọn ọ̀táRẹ yóò fi sìn ọ́.
4. Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ.” Sela