Sáàmù 61:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;Tẹ́tí sí àdúrà mi.

2. Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.

3. Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,ilé ìsọ́ agbára àwọn ọ̀tá.

Sáàmù 61