Sáàmù 58:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòotọ́ẹ̀yin ijọ ènìyàn?Ǹjẹ́ ẹ̀yìn ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?

2. Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìsòdodo,Ọmọ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.

3. Ní inú ìyá wọn wá, ni eniyàn búburú tí sìnà lojukan náà tí a ti bí wọnwọn a máa ṣèké.

4. Ọ̀rọ̀ wọn dà bí ọ̀rọ̀ ejò,gẹ́gẹ́ bí ti sèbé tí ó dítí Rẹ̀,wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara Rẹ̀ ni etí

Sáàmù 58