Sáàmù 53:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Asiwèrè wí ní ọkàn Rẹ̀ pé:“Ọlọ́run kò sí.”Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú;kò sì sí ẹnìkan tí ń ṣe rere.

2. Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀runsórí àwọn ọmọ ènìyànláti wò bóyá ẹnìkan wà tí ó ní òye,tí ó sì ń wá Ọlọ́run.

3. Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà,wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́;kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.

4. Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀?Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹuntí wọn kò sì pe Ọlọ́run?

Sáàmù 53