Sáàmù 51:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Pa ojú Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mikí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédé mi rẹ́.

10. Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.

11. Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú Rẹ̀kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ mi.

12. Mú ayọ̀ ìgbàlà Rẹ̀ tọ̀ mí wákí o sì fún mí ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.

13. Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ àwọn Olùrékọjá ní ọ̀nà Rẹ̀,àwọn ẹlẹ́sẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.

Sáàmù 51