Sáàmù 51:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé ísópù, èmi yóò sì mọ́;fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju sínóò lọ.

8. Jẹ́ kí ń gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;jẹ́ kí gbogbo egúngún tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.

9. Pa ojú Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mikí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédé mi rẹ́.

10. Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.

11. Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú Rẹ̀kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ mi.

12. Mú ayọ̀ ìgbàlà Rẹ̀ tọ̀ mí wákí o sì fún mí ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.

13. Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ àwọn Olùrékọjá ní ọ̀nà Rẹ̀,àwọn ẹlẹ́sẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.

14. Gbàmí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run,ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi,ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo Rẹ kíkan.

Sáàmù 51