Sáàmù 51:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ní tòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.

6. Ní tòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀ kọ̀.

7. Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé ísópù, èmi yóò sì mọ́;fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju sínóò lọ.

8. Jẹ́ kí ń gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;jẹ́ kí gbogbo egúngún tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.

9. Pa ojú Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mikí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédé mi rẹ́.

Sáàmù 51