Sáàmù 51:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.

11. Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú Rẹ̀kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ mi.

12. Mú ayọ̀ ìgbàlà Rẹ̀ tọ̀ mí wákí o sì fún mí ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.

13. Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ àwọn Olùrékọjá ní ọ̀nà Rẹ̀,àwọn ẹlẹ́sẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.

14. Gbàmí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run,ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi,ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo Rẹ kíkan.

15. Olúwa, sí mi ní ètè mi gbogbo,àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn Rẹ̀.

16. Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá;Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọọrẹ̀-ẹbọ sísun

17. Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbínújẹ́ ọkan ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.

Sáàmù 51