Sáàmù 43:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Dámiláre, Ọlọ́run mi,kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè aláìwà-bí-Ọlọ́run:yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.

2. Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?

3. Ran ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ Rẹ jáde,jẹ́ kí wọn ó máa dààbò bò mí;jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ Rẹ,sí ibi tí ìwọ ń gbé.

Sáàmù 43