Sáàmù 41:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.

11. Èmi mọ̀ pé inú Rẹ̀ dùn sí mi,nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.

12. Bí ó ṣe tèmi niìwọ dì mí mú nínú ìwà òtítọ́ miìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú Rẹ títí láé.

13. Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lìláé àti láéláé.Àmín àti Àmín.

Sáàmù 41