Sáàmù 37:29-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.

30. Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,ahọ́n Rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.

31. Òfin Ọlọ́run Rẹ̀ ń bẹní àyà wọn;àwọn ìgbẹ́sẹ̀ Rẹ̀ kì yóò yẹ̀.

32. Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo,Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.

33. Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́kì yóò sì dá a lẹ́bi,nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ Rẹ̀.

34. Dúró de Olúwa,kí o sì má a pa ọ̀nà Rẹ̀ mọ́,yóò sì gbé ọ lékèláti jogún ilẹ̀ náà:Nígbà tí a bágé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.

Sáàmù 37