12. Ènìyàn búburú di rìkísí sí olóòtọ́,wọ́n sì pa ẹyín wọn keke sí wọn;
13. Ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rin-un síàwọn ènìyàn búburú,nítorí tí ó rí wí péọjọ́ wọn ń bọ̀.
14. Ènìyàn búburú fa idà yọ,wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn,láti sọ talákà àti aláìní kalẹ̀,láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.
15. Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ,àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.
16. Ohun díẹ̀ tí olódodo nísàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú.