20. Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà,ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tànsí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà.
21. Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi;wọ́n sọ wí pé,“Áà! Áà!Ojú wa sì ti rí i.”
22. Ìwọ́ ti ríiÌwọ Olúwa:Má ṣe dákẹ́!Ìwọ Olúwa,Má ṣe jìnnà sí mi!
23. Jí dìde!Ru ara Rẹ̀ sókè fún ààbò mi,fún ìdí mi,Ọlọ́run mi àti Olúwa mi!
24. Dá mi láre,ìwọ Olúwa,Ọlọ́run mi,gẹ́gẹ́ bí òdodo Rẹ,kí o má sì ṣe jẹ́ kíwọn kí ó yọ̀ lórí mi!