16. Àwọn àgàbàgebè ń ṣe yẹ̀yẹ́mi ṣíwájú àti sí wájú síiwọ́n pa eyín wọnkeke sí mi.
17. Yóò ti pẹ́tó,ìwọ Olúwa,tí ìwọ yóò máa wò wọ́n lọ?Yọ mí kúrò nínú ìparun wọnàní ẹ̀mí i mi kúrò lọ́wọ́ kìnnìún.
18. Nígbà náà ni èmi yóò sọpẹ́ fún Ọnínú àjọ ńlá;èmi yóò máa yìn Ọ́ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn.
19. Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń ṣe ọ̀tá mikí ó yọ̀ lórí ì mi,tàbí àwọn tí ó kórìírá miní àìní dí máa sẹ́jú sí mi.
20. Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà,ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tànsí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà.