Sáàmù 34:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;ìyìn Rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.

2. Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.

3. Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ Rẹ̀ lékè.

4. Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.

Sáàmù 34