Sáàmù 31:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká;tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi,wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí miláti gba ẹ̀mi mi.

14. Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ OlúwaMo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”

15. Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ Rẹ;gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá miàti àwọn onínúnibíni.

Sáàmù 31